ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ NÍ ÀGBÁYÉ: ÌLỌ́WỌ́SÍ Ọ̀DỌ́ FÚN ÌGBÉSẸ̀ ÀGBÁYÉ.
"ÀYÁJỌ́ ỌJỌ́ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ NÍ ÀGBÁYÉ: ÌLỌ́WỌ́SÍ Ọ̀DỌ́ FÚN ÌGBÉSẸ̀ ÀGBÁYÉ.
~ ADÉKÚNLÉ JÓNÍSẸ.
(Kunlejonise@gmail.com)."
Ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹjọ Ọdọdún Ni Àjọ Àpapọ Orílé-èdè Yáà Sọ́tọ̀ Láti ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Ní Àgbáyé.
Àkòrí fún Àyájọ́ àwọn ọ̀dọ́ Àgbáyé ti Ọdún yìí ni "Ìlọ́wọ́sí Àwọn Ọ̀dọ́ Fún Ìgbésè Àgbáyé". Àkòrí Ọdún yìí fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ibéèrè àti àkòrí bíi : Kíni àwọn ìyọrísí tí o ṣeéṣe tàbí àwọn àbájádèe Nígbàtí a fún àwọn Ọ̀dọ́ ní ààyè láti ṣe alábàpíín? Ìdojúko àwọ̀n Ọ̀dọ́ àti ọ̀nà àbáyọ, Kíni ẹ̀tọ́ tí àwọn Olórí Ìjọba ń ṣe láti ran àwọn Ọ̀dọ́ lọ́wọ́?" Àwon ibéèrè àti àkòrí wọ̀ǹyíì ni ó ń bẹ̀bẹ fún ìdáhùn.
Tani Ọ̀dọ́? Àjọ Àpapọ̀ Orílè-èdè, fún ẹ̀ka Àwọn Ìdí, Ṣàlàyé 'Ọ̀dọ́', bíi àwọn ènìyàn láàrín ọjọ́-orí ọdún mẹ́rìndílógún sí ọdún mẹ́rinlélógún, láìsí ìkórira sí mìíràn àwọn àsọyé nípasẹ̀ àwọn Ìpínlẹ̀ ọmọ ẹgbé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìwádìí fi hàn pé ìpín ogójì nínú Ọgọ́rùn-ń lọ́nà Ẹgbẹ̀rún Ògún Ọ̀dọ́ Ló ń Kópa Nínú Òṣèlú Àti Ìṣèjọba ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀, Èyí Túmọ̀ Sípé Àwọn Àgbàlagbà Ni Olórí Ìjọba Ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀. Òfin Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orílè-èdè Kò Fi Àyè Sílẹ̀ Fún Ìkópa Àwọn Ọ̀dọ́ Nínú Ètò Òṣèlú Àti ìṣèjọba, Ìdí Nìyí Tí Àwọn Ẹgbẹ́ Ajìjàngbara, Ẹgbẹ́ Ìlọsíwájú Àwùjọ Bíi "YIAGA AFRICA" Ti Orílè-èdè "NIGERIA", Àti Ẹgbẹ́ Òṣèlú ṣe ń ṣe Kòkárí Ìpolongo Fífún Àwọn Ọ̀dọ́ Lááyé Láti Kópa Nínú Ìjọba Àti Ètò Òṣèlú, Eléyìí Sì So Èso Rere Ní Orílè-èdè " Nigeria" Nìgbáti Ààrẹ Orílè-èdè Náà, Muhammadu BUHARI Fi Ọwọ́ Sí Ìwé Àbádòfin Tí Ó Fún Àwọn Ọ̀dọ́ Láyè Láti Dupò òṣèlú Àti Láti Kópa Nínú Ètò Ìsèjọba Ní Ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣú Kárùn-ń, Ọdún 2018.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìṣòro Ni Àwọn Ọ̀dọ́ ń Dojúkọ́, Èyí Sí ń Fa Ìfàsẹ́yìn Fún Ọ̀dọ́ Àti Orílè-èdè Lápapọ̀. Ẹ̀kọ́ Ìwọ̀-oòrùn Jẹ́ ọ̀kan Gbòógì Lára Ìṣòro Àwọn Ọ̀dọ́ Adúláwọ̀, Ìdá Ọ̀gọ́ta Nínú Ọgọ́rùn-ń Àwọ́n Ọ̀dọ́ Adúláwọ̀ Ní Kò Sí Ní Ilè-Ìwé Gẹ́gẹ́ Bíí Ìwádìí Àjọ Àpapọ̀ Orílè-èdè Ní Odún 2016, Ewú ńlá Ni Èyí Sì Jẹ́ Fún ọjọ́ ọ̀la Ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Ṣẹ́gun Èyí Ni Sísọ Ètò Ẹ̀kọ́ Di Ọ̀fẹ́ Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ́ẹ́rèẹ̀ Àti Ilé Ẹ̀kọ́ Girama. Síṣètò Àwọn ńkan Amáyédẹrùn Bíi Ilé-ẹ̀kọ́ Tí Ó Bá Ìgbà Mú, Ìwé, Àyìká Tó Gbafẹ́, Àti Olùkọ́ Tó Yanrantí.
Fífún Àwọn Obìnrin Ní Àǹfàní Tí Àwọn Ọ̀kùnrin Ní Láti Kópa Nínú Ètò Ìsèjọba Ati Òṣèlú Yóò Jẹ́ Ìmúṣẹ Ìmúdọ́gba Ẹ̀yà. Gẹ́gẹ́ bí Ìwádìí Àjọ Àpapọ̀Orílè-èdè Ní Ọ̀dún 2019, Ìdá Métàlélógún Nínú Ọgọ́rùn-ń Obìnrín Ló ń Kópa Nínú Ètò Ìṣejóba Àti Òṣèlú Ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀, Èyí Tí Ó Kéré Sí Òṣùwọ̀n Tí Àjọ Àpapọ̀ Orílè-èdè Fojú sùn Sí.
Yorùbá Bọ̀, Wọ́nní "Tí Ara Ilé Ẹni Bá ń Jẹ Kòkòrò Burúkú, Tá Ò Bá Sọfun, Èrèúrú ọ̀nà Ọ̀fun ẹ Kòní Jẹ́ A Sùn Lórùu", Bí A Bá ṣe ń Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Ìṣòro Tí Àwọ́n Ọ̀dọ́ ń Dojúkọ, Óya Kí A Mú ẹnu Ba Àwọn Ìwà Tí Kòbójúmu Tí Àwọn Ọ̀dọ́ ń Wù, Àwọn Ìwà Bíi Lílu Jìbìtì Lórí Ẹ̀rọ Ayélujára, Ìfipábánilòpọ̀, Ìwa Jàndùkú, ABBL. Láàríín Oṣù Kẹta Sí Àkókò Yìí, Ó Ti Tó Obìnrin Métàlélọ́gbọ̀n Tí Wọ́n Ti Fipá Bálòpọ̀Ní Orílè-èdè Nigeria Nìkan, Ìwà Yí Síì ń Peléke Si Lójojúmọ́. Ìbẹ̀rùbọjọ Àti Tífura Tìfura L'àwọn Obìnrin Fi ń Rìn L'áwùjọ̀. Òkánjúà Àti Àìníìtẹ̀ẹ́lọ́rùn Ti Mú Ọ̀pọ̀lọpọ̀Àwọn Ọ̀dọ́ Máa Lu Jìbìtì L'órí Ẹ̀rọ Ayélujára, Yàtọ̀ Sí Pé Ìwà Yí ń Kò kó èrè Bá Orílè-èdè Yíì, Kò Tún Jẹ́ Kí Àwọn Ọ̀dọ́ Tẹ́ Ipá Mó'ṣẹ́ Owó Tàbí F'ojú Sí Ẹ̀kọ́ Wọn. Síṣe Òfin Tí Ó Koròoju Sí Irú Ìwà Bẹ́ẹ̀ Yìí Ò Mú Òpin Bá Ìwà Náà Ní Àwùjọ Wa.
Àfojúsùn Àjọ̀Àpapọ̀ Orílè-èdè Léè Wá Sí Ìmúṣẹ Tí A Bá ṣe Àtúnṣe Sí Àwọn Kùdìẹ̀ Kudiẹ Tí Ó Wà L'áwùjọ̀, Òfin Orílè-èdè, Ẹgbẹ́ Àti Ètò Òṣèlú Wa, Kí A Fi Àyè Sílẹ̀ Fún Àwọn Obìnrin Láti Kópa, Kí Àwọn Ẹgbẹ́ Òṣèlú Máa ṣe Àwọn Ohun Amúnisásẹ́yìn Bíi Gbígba Owó Gọbọi L'ọ́wọ́ Àwọn Olùdíje Àti Màgò Mágó Nínú Ètò Ìdìbò Yálà Abélé Ni, Tàbí Gbogbo Ogbò. Kí A ṣe Ìpolongo Àti Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Fún Àwọn Ọ̀dọ́ Lórí Ọ̀nà Tí Wọ́n Fi Gbúdọ̀ Yẹra Fún Àwọn Ìwà Tí Ò Dáa L'áwùjọ̀ Bíi Ìfinípábánilopọ̀, Lí'lu Jìbìtì, Jàgídíjàgan, Kí Wọ́n Síì F'ojú Sí Ẹ̀kọ́ Wọn.
Aku ayoja Ojo awon odo o!
ReplyDeleteE Seun Bàbá Àgbà.
ReplyDeleteAku ayajo odun awa odo oo, oluwa o pawamo lati dagba
ReplyDeleteÀmín Àse.
DeleteOgbeni Jojuade, eku ilaniloye.
ReplyDeleteE Seun Bàbá Àgbà.
DeleteẸ ṣé fún àròkọ yìí. Àdùrá wa ni wípé àwọn ọ̀dọ́ wa á yí ìwà wọn padà sí rere.
ReplyDeleteÀmín Àse. E Seun Bàbá Àgbà.
DeleteMi o le ka daradara sugbon ise lo se..kaare lai
Delete